1. LẸHIN nkan wọnyi Jesu nrìn ni Galili: nitoriti kò fẹ rìn ni Judea, nitori awọn Ju nwá ọ̀na ati pa a.
2. Ajọ awọn Ju ti iṣe ajọ ìpagọ́, sunmọ etile tan.
3. Nitorina awọn arakunrin rẹ̀ wi fun u pe, Lọ kuro nihinyi, ki o si lọ si Judea, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ pẹlu ki o le ri iṣẹ rẹ ti iwọ nṣe.
4. Nitoripe kò si ẹnikẹni ti iṣe ohunkohun nikọ̀kọ, ti on tikararẹ̀ si nfẹ ki a mọ̀ on ni gbangba. Bi iwọ ba nṣe nkan wọnyi, fi ara rẹ hàn fun araiye.
5. Nitoripe awọn arakunrin rẹ̀ kò tilẹ gbà a gbọ́.
6. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Akokò temi kò ti ide: ṣugbọn akokò ti nyin ni imura tan nigbagbogbo.
7. Aiye kò le korira nyin; ṣugbọn emi li o korira, nitoriti mo jẹri gbe e pe, iṣẹ rẹ̀ buru.
8. Ẹnyin ẹ gòke lọ si ajọ yi: emi kì yio ti igoke lọ si ajọ yi; nitoriti akokò temi kò ti ide.