Joh 5:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Bi Jesu ti ri i ni idubulẹ, ti o si mọ̀ pe, o pẹ ti o ti wà bẹ̃, o wi fun u pe, Iwọ fẹ ki a mu ọ larada bi?

7. Abirùn na da a lohùn wipe, Ọgbẹni, emi kò li ẹni, ti iba gbé mi sinu adagun, nigbati a ba nrú omi na: bi emi ba ti mbọ̀ wá, ẹlomiran a sọkalẹ sinu rẹ̀ ṣiwaju mi.

8. Jesu wi fun u pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã rin.

9. Lọgan a si mu ọkunrin na larada, o si gbé akete rẹ̀, o si nrìn. Ọjọ na si jẹ ọjọ isimi.

10. Nitorina awọn Ju wi fun ọkunrin na ti a mu larada pe, Ọjọ isimi li oni: kò tọ́ fun ọ lati gbé akete rẹ.

11. O si da wọn lohùn wipe, Ẹniti o mu mi larada, on li o wi fun mi pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn.

12. Nigbana ni nwọn bi i lẽre wipe, ọkunrin wo li ẹniti o wi fun ọ pe, Gbé akete rẹ, ki o si ma rìn?

13. Ẹniti a mu larada na kò si mọ̀ ẹniti iṣe: nitori Jesu ti kuto nibẹ̀, nitori awọn enia pipọ wà nibẹ̀.

14. Lẹhinna Jesu ri i ni tẹmpili o si wi fun u pe, Wo o, a mu ọ larada: máṣe dẹṣẹ mọ́, ki ohun ti o buru jù yi lọ ki o má bà ba ọ.

Joh 5