Joh 5:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN nkan wọnyi ajọ awọn Ju kan kò; Jesu si gòke lọ si Jerusalemu.

2. Adagun omi kan si wà ni Jerusalemu, leti bodè agutan, ti a npè ni Betesda li ède Heberu, ti o ni iloro marun.

3. Ninu wọnyi li ọ̀pọ awọn abirùn enia gbé dubulẹ si, awọn afọju, arọ ati awọn gbigbẹ, nwọn si nduro dè rirú omi.

4. Nitori angẹli a ma digbà sọkalẹ lọ sinu adagun na, a si ma rú omi: lẹhin igbati a ba ti rú omi na tan ẹnikẹni ti o ba kọ́ wọ̀ inu rẹ̀, a di alaradidá ninu arùnkárun ti o ni.

5. Ọkunrin kan si wà nibẹ̀, ẹniti o wà ni ailera rẹ̀ li ọdún mejidilogoji.

6. Bi Jesu ti ri i ni idubulẹ, ti o si mọ̀ pe, o pẹ ti o ti wà bẹ̃, o wi fun u pe, Iwọ fẹ ki a mu ọ larada bi?

7. Abirùn na da a lohùn wipe, Ọgbẹni, emi kò li ẹni, ti iba gbé mi sinu adagun, nigbati a ba nrú omi na: bi emi ba ti mbọ̀ wá, ẹlomiran a sọkalẹ sinu rẹ̀ ṣiwaju mi.

8. Jesu wi fun u pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã rin.

9. Lọgan a si mu ọkunrin na larada, o si gbé akete rẹ̀, o si nrìn. Ọjọ na si jẹ ọjọ isimi.

10. Nitorina awọn Ju wi fun ọkunrin na ti a mu larada pe, Ọjọ isimi li oni: kò tọ́ fun ọ lati gbé akete rẹ.

11. O si da wọn lohùn wipe, Ẹniti o mu mi larada, on li o wi fun mi pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn.

Joh 5