Joh 3:32-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Ohun ti o ti ri ti o si ti gbọ́ eyina si li on njẹri rẹ̀; ko si si ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀.

33. Ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀ fi edidi di i pe, otitọ li Ọlọrun.

34. Nitori ẹniti Ọlọrun ti rán nsọ ọ̀rọ Ọlọrun: nitoriti Ọlọrun kò fi Ẹmí fun u nipa oṣuwọn.

35. Baba fẹ Ọmọ, o si ti fi ohun gbogbo le e lọwọ.

36. Ẹniti o ba gbà Ọmọ gbọ́, o ni iye ainipẹkun: ẹniti kò ba si gbà Ọmọ gbọ, kì yio ri ìye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun mbẹ lori rẹ̀.

Joh 3