Joh 3:12-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Bi mo ba sọ̀ ohun ti aiye yi fun nyin, ti ẹnyin kò si gbagbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbagbọ́ bi mo ba sọ ohun ti ọrun fun nyin?

13. Ko si si ẹniti o gòke re ọrun, bikoṣe ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ani Ọmọ-enia ti mbẹ li ọrun.

14. Bi Mose si ti gbé ejò soke li aginjù, gẹgẹ bẹ̃li a kò le ṣe alaigbé Ọmọ-enia soke pẹlu:

15. Ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ, ki o má ba ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.

16. Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ má bà ṣegbé, ṣugbọn ki o le ni ìye ainipẹkun.

17. Nitori Ọlọrun kò rán Ọmọ rẹ̀ si aiye lati da araiye lẹjọ; ṣugbọn ki a le ti ipasẹ rẹ̀ gbà araiye là.

18. Ẹniti o ba gbà a gbọ́, a ko ni da a lẹjọ; ṣugbọn a ti da ẹniti kò gbà a gbọ́ lẹjọ na, nitoriti kò gbà orukọ Ọmọ bíbi kanṣoṣo ti Ọlọrun gbọ́.

19. Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru.

20. Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí.

21. Ṣugbọn ẹniti o ba nṣe otitọ ni iwá si imọlẹ, ki iṣẹ rẹ̀ ki o le fi ara hàn pe, a ṣe wọn nipa ti Ọlọrun.

22. Lẹhin nkan wọnyi Jesu pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá si ilẹ Judea; o si duro pẹlu wọn nibẹ o si baptisi.

23. Johanu pẹlu si mbaptisi ni Ainoni, li àgbegbe Salimu, nitoriti omi pipọ wà nibẹ̀: nwọn si nwá, a si baptisi wọn.

24. Nitoriti a kò ti isọ Johanu sinu tubu.

25. Nigbana ni iyàn kan wà larin awọn ọmọ-ẹhin Johanu, pẹlu Ju kan niti ìwẹnu.

26. Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá.

27. Johanu dahùn o si wipe, Enia ko le ri nkankan gbà, bikoṣepe a ba ti fifun u lati ọrun wá.

28. Ẹnyin tikaranyin jẹri mi, pe mo wipe, Emi kì iṣe Kristi na, ṣugbọn pe a rán mi ṣiwaju rẹ̀.

29. Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.

30. On kò le ṣaima pọsi i, ṣugbọn emi kò le ṣaima rẹ̀hin.

Joh 3