Joh 3:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌKUNRIN kan si wà ninu awọn Farisi, ti a npè ni Nikodemu, ijoye kan ninu awọn Ju:

2. On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.

3. Jesu dahùn o si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun.

4. Nikodemu wi fun u pe, A o ti ṣe le tún enia bí, nigbati o di agbalagba tan? o ha le wọ̀ inu iya rẹ̀ lọ nigba keji, ki a si bí i?

5. Jesu dahùn wipe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a fi omi ati Ẹmi bi enia, on kò le wọ̀ ijọba Ọlọrun.

6. Eyiti a bí nipa ti ara, ara ni; eyiti a si bí nipa ti Ẹmí, ẹmí ni.

7. Ki ẹnu ki o máṣe yà ọ, nitori mo wi fun ọ pe, A kò le ṣe alaitún nyin bí.

8. Afẹfẹ nfẹ si ibi ti o gbé wù u, iwọ si ngbọ́ iró rẹ̀, ṣugbọn iwọ kò mọ̀ ibi ti o ti wá, ati ibi ti o gbé nlọ: gẹgẹ bẹ̃ni olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ẹmí.

9. Nikodemu dahùn, o si wi fun u pe, Nkan wọnyi yio ti ṣe le ri bẹ̃?

Joh 3