1. ỌKUNRIN kan si wà ninu awọn Farisi, ti a npè ni Nikodemu, ijoye kan ninu awọn Ju:
2. On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.
3. Jesu dahùn o si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun.
4. Nikodemu wi fun u pe, A o ti ṣe le tún enia bí, nigbati o di agbalagba tan? o ha le wọ̀ inu iya rẹ̀ lọ nigba keji, ki a si bí i?