8. Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹhin iyoku mu ọkọ̀ kekere kan wá (nitoriti nwọn kò jina silẹ, ṣugbọn bi iwọn igba igbọnwọ); nwọn nwọ́ àwọn na ti o kún fun ẹja.
9. Nigbati nwọn gúnlẹ, nwọn ri iná ẹyín nibẹ, ati ẹja lori rẹ̀, ati akara.
10. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ mú ninu ẹja ti ẹ pa nisisiyi wá.
11. Nitorina Simoni Peteru gòke, o si fà àwọn na wálẹ, o kún fun ẹja nla, o jẹ mẹtalelãdọjọ: bi nwọn si ti pọ̀ to nì, àwọn na kò ya.
12. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ wá jẹun owurọ̀. Kò si si ẹnikan ninu awọn ọmọ-ẹhin ti o jẹ bi i pe, Tani iwọ iṣe? nitoriti nwọn mọ̀ pe Oluwa ni.
13. Jesu wá, o si mu akara, o si fifun wọn, gẹgẹ bẹ̃ si li ẹja.
14. Eyi ni igba kẹta nisisiyi ti Jesu farahàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú.
15. Njẹ lẹhin igbati nwọn jẹun owurọ̀ tan, Jesu wi fun Simoni Peteru pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi jù awọn wọnyi lọ bi? O si wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn ọdọ-agutan mi.
16. O tún wi fun u nigba keji pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ mi bi? O wi fun u pe, Bẹ̃ni Oluwa; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. O wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi.