Joh 16:21-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye.

22. Nitorina ẹnyin ni ibinujẹ nisisiyi: ṣugbọn emi o tún ri nyin, ọkàn nyin yio si yọ̀, kò si si ẹniti yio gbà ayọ̀ nyin lọwọ nyin.

23. Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin.

24. Titi di isisiyi ẹ kò ti ibère ohunkohun li orukọ mi: ẹ bère, ẹ o si ri gbà, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.

25. Nkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun nyin: ṣugbọn akokò de, nigbati emi kì yio fi owe ba nyin sọrọ mọ́, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun nyin gbangba.

26. Li ọjọ na ẹnyin o bère li orukọ mi: emi kò si wi fun nyin pe, emi o bère lọwọ Baba fun nyin:

Joh 16