40. O ti fọ́ wọn loju, o si ti se àiya wọn le; ki nwọn má ba fi oju wọn ri, ki nwọn má ba fi ọkàn wọn mọ̀, ki nwọn má ba yipada, ki emi má ba mu wọn larada.
41. Nkan wọnyi ni Isaiah wi, nitori o ti ri ogo rẹ̀, o si sọ̀rọ rẹ̀.
42. Sibẹ ọ̀pọ ninu awọn olori gbà a gbọ́ pẹlu; ṣugbọn nitori awọn Farisi nwọn kò jẹwọ rẹ̀, ki a má bà yọ wọn kuro ninu sinagogu:
43. Nitori nwọn fẹ iyìn enia jù iyìn ti Ọlọrun lọ.
44. Jesu si kigbe o si wipe, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, emi kọ li o gbàgbọ́, ṣugbọn ẹniti o rán mi.
45. Ẹniti o ba si ri mi, o ri ẹniti o rán mi.
46. Emi ni imọlẹ ti o wá si aiye, ki ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́ ki o máṣe wà li òkunkun.
47. Bi ẹnikẹni ba si gbọ́ ọ̀rọ mi, ti kò si pa wọn mọ, emi kì yio ṣe idajọ rẹ̀: nitoriti emi kò wá lati ṣe idajọ aiye, bikoṣe lati gbà aiye là.
48. Ẹniti o ba kọ̀ mi, ti kò si gbà ọ̀rọ mi, o ni ẹnikan ti nṣe idajọ rẹ̀: ọ̀rọ ti mo ti sọ, on na ni yio ṣe idajọ rẹ̀ ni igbẹhin ọjọ.
49. Nitori emi kò dá ọrọ sọ fun ara mi, ṣugbọn Baba ti o rán mi, on li o ti fun mi li aṣẹ, ohun ti emi o sọ, ati eyiti emi o wi.
50. Emi si mọ̀ pe ìye ainipẹkun li ofin rẹ̀: nitorina, ohun wọnni ti mo ba wi, gẹgẹ bi Baba ti sọ fun mi, bẹ̀ni mo wi.