Joh 10:30-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Ọ̀kan li emi ati Baba mi jasi.

31. Awọn Ju si tún he okuta, lati sọ lù u.

32. Jesu da wọn lohùn pe, Ọpọlọpọ iṣẹ rere ni mo fi hàn nyin lati ọdọ Baba mi wá; nitori ewo ninu iṣẹ wọnni li ẹnyin ṣe sọ mi li okuta?

33. Awọn Ju si da a lohùn, wipe, Awa kò sọ ọ li okuta nitori iṣẹ rere, ṣugbọn nitori ọrọ-odi: ati nitori iwọ ti iṣe enia nfi ara rẹ ṣe Ọlọrun.

34. Jesu da wọn lohùn pe, A kò ha ti kọ ọ ninu ofin nyin pe, Mo ti wipe, ọlọrun li ẹnyin iṣe?

35. Bi o ba pè wọn li ọlọrun, awọn ẹniti a fi ọ̀rọ Ọlọrun fun, a kò si le ba iwe-mimọ́ jẹ,

36. Ẹnyin ha nwi niti ẹniti Baba yà si mimọ́, ti o si rán si aiye pe, Iwọ nsọrọ-odi, nitoriti mo wipe Ọmọ Ọlọrun ni mi?

37. Bi emi kò ba ṣe iṣẹ Baba mi, ẹ máṣe gbà mi gbọ́.

Joh 10