5. Imọlẹ na si nmọlẹ ninu òkunkun; òkunkun na kò si bori rẹ̀.
6. Ọkunrin kan wà ti a rán lati ọdọ Ọlọrun wá, orukọ ẹniti njẹ Johanu.
7. On na li a si rán fun ẹri, ki o le ṣe ẹlẹri fun imọlẹ na, ki gbogbo enia ki o le gbagbọ́ nipasẹ rẹ̀.
8. On kì iṣe imọlẹ̀ na, ṣugbọn a rán a wá lati ṣe ẹlẹri fun Imọlẹ na.
9. Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye.
10. On si wà li aiye, nipasẹ rẹ̀ li a si ti da aiye, aiye kò si mọ̀ ọ.
11. O tọ̀ awọn tirẹ̀ wá, awọn ará tirẹ̀ kò si gbà a.