1. NITORINA kiyesi i, li ọjọ wọnni, ati li akokò na, nigbati emi o tun mu igbèkun Juda ati Jerusalemu padà bọ̀.
2. Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifojì Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ̀ nitori awọn enia mi, ati nitori Israeli iní mi, ti nwọn ti fọ́n ka sãrin awọn orilẹ̀-ede, nwọn si ti pín ilẹ mi.
3. Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu.
4. Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin.