21. Olõtọ ni mo ṣe, sibẹ emi kò kiyesi ẹmi mi, ìwa mi li emi iba ma gàn.
22. Ohun kanna ni, nitorina ni emi ṣe sọ ọ: on a pa ẹni-otitọ ati enia buburu pẹlu.
23. Bi jamba ba pa ni lojijì, yio rẹrin idanwo alaiṣẹ̀.
24. A fi aiye le ọwọ enia buburu; o si bò awọn onidajọ rẹ̀ li oju; bi kò ba ri bẹ̃, njẹ tani?
25. Njẹ nisisiyi ọjọ mi yara jù onṣẹ lọ, nwọn fò lọ, nwọn kò ri ire.
26. Nwọn kọja lọ bi ọkọ-ẽsú ti nsure lọ; bi idì ti o nyara si ohun ọdẹ.
27. Bi emi ba wipe, emi o gbagbe aro ibinujẹ mi, emi o fi ọkàn lelẹ̀, emi o si rẹ̀ ara mi lẹkun.
28. Ẹ̀ru ibinujẹ mi gbogbo bà mi, emi mọ̀ pe iwọ kì yio mu mi bi alaiṣẹ̀.
29. Bi o ba ṣepe enia buburu li emi, njẹ kili emi nṣe lãlã lasan si!
30. Bi mo tilẹ fi omi òjo didì wẹ̀ ara mi, ti mo fi omi-aró wẹ̀ ọwọ mi mọ́,
31. Sibẹ iwọ o gbe mi bọ̀ inu ihò ọ̀gọdọ, aṣọ ara mi yio sọ mi di ẹni-irira.
32. Nitori on kì iṣe enia bi emi, ti emi o fi da a lohùn ti awa o fi pade ni idajọ.