Job 9:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JOBU si dahùn o si wipe,

2. Emi mọ̀ pe bẹ̃ni nitõtọ! bawo li enia yio ha ti ṣe alare niwaju Ọlọrun?

3. Bi o ba ṣepe yio ba a jà, on kì yio lè idá a lohùn kan ninu ẹgbẹrun ọ̀ran.

4. Ọlọgbọ́n-ninu ati alagbara ni ipá li on; tali o ṣagidi si i, ti o si gbè fun u ri?

5. Ẹniti o ṣi okè ni idi, ti nwọn kò si mọ̀: ti o tari wọn ṣubu ni ibinu rẹ̀.

6. Ti o mì ilẹ aiye tìti kuro ni ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ si mì tìti.

7. Ti o paṣẹ fun õrùn, ti on kò si là, ti o si dí irawọ̀ mọ́.

8. On nikanṣoṣo li o na oju ọrun lọ, ti o si nrìn lori ìgbì okun.

9. Ẹniti o da irawọ̀ Arketuru, Orioni ati Pleiade ati iyàra pipọ ti gusu.

10. Ẹniti nṣe ohun ti o tobi jù awari lọ, ani ohun iyanu laini iye.

11. Kiyesi i, on kọja lọ li ẹ̀ba ọdọ mi, emi kò si ri i, o si kọja siwaju, bẹ̃li emi kò ri oju rẹ̀.

12. Kiyesi i, o jãgbà lọ, tani yio fa a pada? tani yio bi i pe, kini iwọ nṣe nì?

13. Ọlọrun kò ni fà ibinu rẹ̀ sẹhin, awọn oniranlọwọ ìgberaga a si tẹriba labẹ rẹ̀.

14. Ambọtori emi ti emi o fi dá a lohùn, ti emi o fi má ṣa ọ̀rọ awawì mi ba a ṣawiye?

Job 9