Job 8:20-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Kiyesi i, Ọlọrun kì yio ta ẹni-otitọ nù, bẹ̃ni kì yio ràn oniwa-buburu lọwọ.

21. Titi yio fi fi ẹ̀rin kún ọ li ẹnu, ati ète rẹ pẹlu iho ayọ̀.

22. Itiju li a o fi bò awọn ti o korira rẹ, ati ibujoko enia buburu kì yio si mọ.

Job 8