1. NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe,
2. Iwọ o ti ma sọ nkan wọnyi pẹ to? ti ọ̀rọ ẹnu rẹ yio si ma dabi ẹfufu nla?
3. Ọlọrun a ha ma yi idajọ po bi, tabi Olodumare a ma fi otitọ ṣẹ̀ bi?
4. Nigbati awọn ọmọ rẹ ṣẹ̀ si i, o si gbá wọn kuro nitori irekọja wọn.
5. Bi iwọ ba si kepe Ọlọrun ni igba akokò, ti iwọ bá si gbadura ẹ̀bẹ si Olodumare.