1. NIGBANA ni Jobu da OLUWA lohùn o si wipe,
2. Emi mọ̀ pe, iwọ le iṣe ohun gbogbo, ati pe, kò si iro-inu ti a le ifasẹhin kuro lọdọ rẹ.
3. Tani ẹniti nfi ìgbimọ pamọ laini ìmọ? nitorina ni emi ṣe nsọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye.
4. Emi bẹ̀ ọ, gbọ́, emi o si sọ, emi o bère lọwọ rẹ, ki iwọ ki o si bùn mi ni oye.
5. Emi ti fi gbigbọ́ eti gburo rẹ, ṣugbọn nisisiyi oju mi ti ri ọ.
6. Njẹ nitorina emi korira ara mi, mo si ronupiwada ṣe tóto ninu ekuru ati ẽru.
7. Bẹ̃li o si ri, lẹhin igbati OLUWA ti sọ ọ̀rọ wọnyi tan fun Jobu, OLUWA si wi fun Elifasi, ara Tema pe, Mo binu si ọ ati si awọn ọrẹ́ rẹ mejeji, nitoripe ẹnyin kò sọ̀rọ niti emi, ohun ti o tọ́ bi Jobu iranṣẹ mi ti sọ.