1. NIGBANA ni Jobu da OLUWA lohùn o si wipe,
2. Emi mọ̀ pe, iwọ le iṣe ohun gbogbo, ati pe, kò si iro-inu ti a le ifasẹhin kuro lọdọ rẹ.
3. Tani ẹniti nfi ìgbimọ pamọ laini ìmọ? nitorina ni emi ṣe nsọ eyi ti emi kò mọ̀, ohun ti o ṣe iyanu jọjọ niwaju mi, ti emi kò moye.
4. Emi bẹ̀ ọ, gbọ́, emi o si sọ, emi o bère lọwọ rẹ, ki iwọ ki o si bùn mi ni oye.
5. Emi ti fi gbigbọ́ eti gburo rẹ, ṣugbọn nisisiyi oju mi ti ri ọ.
6. Njẹ nitorina emi korira ara mi, mo si ronupiwada ṣe tóto ninu ekuru ati ẽru.