Job 41:21-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ẹmi rẹ̀ tinabọ ẹyin, ọ̀wọ-iná si ti ẹnu rẹ̀ jade.

22. Li ọrùn rẹ̀ li agbara kù si, ati ibinujẹ aiya si pada di ayọ̀ niwaju rẹ̀.

23. Jabajaba ẹran rẹ̀ dijọ pọ̀, nwọn mura giri fun ara wọn, a kò le iṣi wọn ni ipò.

24. Aiya rẹ̀ duro gbagigbagi bi okuta, ani o le bi iya-ọlọ.

Job 41