Job 40:10-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ.

11. Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ.

12. Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn.

13. Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ.

14. Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la.

15. Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu.

16. Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀.

17. On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.

18. Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin.

19. On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ.

20. Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire.

21. O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ.

22. Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri.

23. Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀.

Job 40