13. Ni iro inu loju iran oru, nigbati orun ìjika kun enia.
14. Ẹ̀ru bà mi ati iwarirì ti o mu gbogbo egungun mi wá pepé.
15. Nigbana ni iwin kan kọja lọ niwaju mi, irun ara mi dide ró ṣanṣan.
16. On duro jẹ, ṣugbọn emi kò le iwò apẹrẹ irí rẹ̀, àworan kan hàn niwaju mi, idakẹ rọrọ wà, mo si gbohùn kan wipe: