1. NIGBANA ni Elifasi, ara Tema, dahùn wipe,
2. Bi awa ba fi ẹnu le e, lati ba ọ sọrọ, iwọ o ha binujẹ? ṣugbọn tali o le pa ọ̀rọ mọ ẹnu laisọ?
3. Kiyesi i, iwọ sa ti kọ́ ọ̀pọ enia, iwọ sa ti mu ọwọ alailera le.
4. Ọ̀rọ rẹ ti gbe awọn ti nṣubu lọ duro, iwọ si ti mu ẽkun awọn ti nwarirì lera.
5. Ṣugbọn nisisiyi o de ba ọ, o si rẹ̀ ọ, o kọlu ọ, ara rẹ kò lelẹ̀.
6. Ibẹru Ọlọrun rẹ kò ha jẹ igbẹkẹle rẹ? ati iduro ṣinṣin si ìwa ọ̀na rẹ kò ha si jẹ abá rẹ?
7. Emi bẹ̀ ọ ranti, tali o ṣegbe ri laiṣẹ̀, tabi nibo li a gbe ké olododo kuro ri?
8. Ani bi emi ti ri rí pe: awọn ti nṣe itulẹ ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si fọ́n irugbin ìwa buburu, nwọn a si ká eso rẹ̀ na.
9. Nipa ifẹsi Ọlọrun nwọn a ṣegbe, nipa ẽmi ibinu rẹ̀ nwọn a parun.
10. Bibu ramuramu kiniun ati ohùn onroró kiniun ati ehin awọn ẹ̀gbọrọ kiniun li a ka.
11. Ogbo kiniun kígbe, nitori airi ohun-ọdẹ, awọn ẹ̀gbọrọ kiniun sisanra li a tukakiri.