Job 38:9-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nigbati mo fi awọsanma ṣe aṣọ rẹ̀, ati òkunkun ṣiṣu ṣe ọ̀ja igbanu rẹ̀?

10. Ti mo ti paṣẹ ipinnu mi fun u, ti mo si ṣe bèbe ati ilẹkun.

11. Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ.

12. Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀?

13. Ki o le idi opin ilẹ aiye mu, ki a le gbọ̀n awọn enia buburu kuro ninu rẹ̀.

14. Ki o yipada bi amọ fun edidi amọ, ki gbogbo rẹ̀ ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ẹnipe ninu aṣọ igunwa.

15. A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́.

16. Iwọ ha wọ inu isun okun lọ ri bi? iwọ si rin lori isalẹ ibú nla?

17. A ha ṣilẹkun ikú silẹ fun ọ ri bi, iwọ si ri ilẹkun ojiji ikú?

Job 38