Job 38:27-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Lati mu ilẹ tutù, ijù ati alairo, ati lati mu irudi ọmudún eweko ru jade?

28. Ojo ha ni baba bi, tabi tali o bi ikán ìsẹ-iri?

29. Lati inu tani ìdi omi ti jade wá, ati ìri didi ọrun tali o bi i?

30. Omi bò o mọlẹ bi ẹnipe labẹ okuta, oju ibú nla si dìlupọ̀.

31. Iwọ le ifi ọja de awọn irawọ meje [Pleyade] tabi iwọ le itudi irawọ Orionu?

32. Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ [Massaroti] jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le iṣe àmọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀?

33. Iwọ mọ̀ ilana-ilana ọrun, iwọ le ifi ijọba rẹ̀ lelẹ li aiye?

34. Iwọ le igbé ohùn rẹ soke de awọsanma, ki ọ̀pọlọpọ omi ki o le bò ọ?

35. Iwọ le iran mànamána ki nwọn ki o le ilọ, ki nwọn ki o si wi fun ọ pe, Awa nĩ!

36. Tali o fi ọgbọ́n si odo-inu, tabi tali o fi oye sinu aiya?

37. Tali o fi ọgbọ́n ka iye awọsanma, tali o si mu igo ọrun dàjade.

38. Nigbati erupẹ di lile, ati ogulutu dipọ̀?

39. Iwọ o ha dẹ ọdẹ fun abo kiniun bi, iwọ o si tẹ́ ebi ẹgbọrọ kiniun lọrun?

40. Nigbati nwọn ba mọlẹ ninu iho wọn, ti nwọn si ba ni ibuba de ohun ọdẹ.

Job 38