23. Ti mo ti fi pamọ de igba iyọnu, de ọjọ ogun ati ijà.
24. Ọ̀na wo ni imọlẹ fi nyà, ti afẹfẹ ila-orun tàn kakiri lori ilẹ aiye?
25. Tali o la ipado fun ẹkún iṣan omi, ati ọ̀na fun manamana ãrá?
26. Lati mu u rọ̀jo sori aiye, nibiti enia kò si, ni aginju nibiti enia kò si.
27. Lati mu ilẹ tutù, ijù ati alairo, ati lati mu irudi ọmudún eweko ru jade?
28. Ojo ha ni baba bi, tabi tali o bi ikán ìsẹ-iri?
29. Lati inu tani ìdi omi ti jade wá, ati ìri didi ọrun tali o bi i?
30. Omi bò o mọlẹ bi ẹnipe labẹ okuta, oju ibú nla si dìlupọ̀.
31. Iwọ le ifi ọja de awọn irawọ meje [Pleyade] tabi iwọ le itudi irawọ Orionu?
32. Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ [Massaroti] jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le iṣe àmọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀?
33. Iwọ mọ̀ ilana-ilana ọrun, iwọ le ifi ijọba rẹ̀ lelẹ li aiye?
34. Iwọ le igbé ohùn rẹ soke de awọsanma, ki ọ̀pọlọpọ omi ki o le bò ọ?
35. Iwọ le iran mànamána ki nwọn ki o le ilọ, ki nwọn ki o si wi fun ọ pe, Awa nĩ!