Job 38:11-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ti mo si wipe, Nihinyi ni iwọ o dé, ki o má si rekọja, nihinyi si ni igberaga riru omi rẹ yio gbe duro mọ.

12. Iwọ paṣẹ fun owurọ lati igba ọjọ rẹ̀ wá, iwọ si mu ila-õrun mọ̀ ipo rẹ̀?

13. Ki o le idi opin ilẹ aiye mu, ki a le gbọ̀n awọn enia buburu kuro ninu rẹ̀.

14. Ki o yipada bi amọ fun edidi amọ, ki gbogbo rẹ̀ ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ẹnipe ninu aṣọ igunwa.

15. A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́.

16. Iwọ ha wọ inu isun okun lọ ri bi? iwọ si rin lori isalẹ ibú nla?

17. A ha ṣilẹkun ikú silẹ fun ọ ri bi, iwọ si ri ilẹkun ojiji ikú?

18. Iwọ̀ moye ibú aiye bi? sọ bi iwọ ba mọ̀ gbogbo rẹ̀?

19. Ọ̀na wo ni imọlẹ igbé, bi o ṣe ti òkunkun, nibo ni ipò rẹ̀?

20. Ti iwọ o fi mu u lọ si ibi àla rẹ̀, ti iwọ o si le imọ̀ ipa-ọ̀na lọ sinu ile rẹ̀?

21. Iwọ mọ̀ eyi, nitoriti ni igbana ni a bi ọ? ati iye ọjọ rẹ si pọ!

22. Iwọ ha wọ inu iṣura ojò-dídì lọ ri bí, iwọ si ri ile iṣura yinyin ri?

23. Ti mo ti fi pamọ de igba iyọnu, de ọjọ ogun ati ijà.

24. Ọ̀na wo ni imọlẹ fi nyà, ti afẹfẹ ila-orun tàn kakiri lori ilẹ aiye?

Job 38