Job 37:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nigbana ni awọn ẹranko iwọnu ihò lọ, nwọn a si wà ni ipò wọn.

9. Lati iha gusu ni ìji ajayika ti ijade wá, ati otutu lati inu afẹfẹ ti tu awọsanma ká.

10. Nipa ẹmi Ọlọrun a fi ìdi-omi funni, ibu-omi a si sunkì.

11. Pẹlupẹlu o fi omi pupọ mu awọsanma wuwo, a si tú awọsanma imọlẹ rẹ̀ ká.

12. Awọn wọnyi ni a si yi kakiri nipa ilana rẹ̀, ki nwọn ki o le iṣe ohunkohun ti o pa fun wọn li aṣẹ loju aiye lori ilẹ.

13. O mu u wá ibãṣe fun ikilọ̀ ni, tabi fun rere ilẹ rẹ̀, tabi fun ãnu.

14. Jobu dẹtisilẹ si eyi, duro jẹ, ki o si rò iṣẹ iyanu Ọlọrun.

15. Iwọ mọ̀ akoko ìgba ti Ọlọrun sọ wọn lọjọ̀, ti o si mu imọlẹ awọsanma rẹ̀ dán?

16. Iwọ mọ̀ ọ̀na ti awọsanma ifo lọ; iṣẹ iyanu ẹniti o pé ni ìmọ?

Job 37