Job 37:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AIYA si fò mi si eyi pẹlu, o si ṣi kuro ni ipò rẹ̀.

2. Fetisilẹ dãda, ki ẹ si gbọ́ iró ohùn rẹ̀, ati iró ti o ti ẹnu rẹ̀ jade wá.

3. O ṣe ilana rẹ̀ nisalẹ abẹ ọrun gbogbo, manamana rẹ̀ ni o si jọwọ rẹ̀ lọwọ de opin ilẹ aiye.

4. Lẹhin manamana ohùn kan fọ̀ ramuramu, o fi ohùn ọlanla rẹ̀ sán ãrá: on kì yio si da ãrá duro nigbati a ba ngbọ́ ohùn rẹ̀.

5. Ọlọrun fi ohùn rẹ̀ sán ãrá iyanilẹnu, ohun nlanla ni iṣe ti awa kò le imọ̀.

6. Nitoriti o wi fun ojo didì pe, Iwọ rọ̀ silẹ aiye, ati pẹlu fun ọwọ ojo, ati fun ojo nla agbara rẹ̀.

7. O fi edidi di gbogbo enia, ki gbogbo wọn ki o le imọ̀ iṣẹ rẹ̀.

Job 37