Job 36:14-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nigbana ni ọkàn wọn yio kú li ewe, ẹmi wọn a si wà ninu awọn oniwa Sodomu.

15. On gba otoṣi ninu ipọnju rẹ̀, a si ṣi wọn li eti ninu inilara.

16. Bẹ̃ni pẹlupẹlu o si dẹ̀ ọ lọ lati inu ihagaga si ibi gbõrò, ti kò ni wahala ninu rẹ̀; ati ohun ti a si gbe kalẹ ni tabeli rẹ, a jẹ kiki ọ̀ra.

17. Ṣugbọn iwọ kún fun idajọ awọn enia buburu; idajọ ati otitọ di ọ mu.

18. Nitori ibinu mbẹ, ṣọra ki titó rẹ ma bà tàn ọ lọ; má si ṣe jẹ ki titobi irapada mu ọ ṣìna.

19. Ọrọ̀ rẹ pọ̀ to, ti wahala kì yio fi de ba ọ bi? tabi ipá agbara rẹ?

20. Má ṣe ifẹ oru, nigbati a nke awọn orilẹ-ède kuro ni ipo wọn.

21. Ma ṣọra ki iwọ ki o má yi ara rẹ pada si asan, nitori eyi ni iwọ ti ṣàyan jù sũru lọ.

Job 36