11. Bi nwọn ba gbagbọ, ti nwọn si sin i, nwọn o lò ọjọ wọn ninu ìrọra, ati ọdun wọn ninu afẹ́.
12. Ṣugbọn bi nwọn kò ba gbagbọ, nwọn o ti ọwọ idà ṣègbe, nwọn a si kú laini oye.
13. Ṣugbọn awọn àgabagebe li aiya kó ibinu jọ; nwọn kò kigbe nigbati o ba dè wọn.
14. Nigbana ni ọkàn wọn yio kú li ewe, ẹmi wọn a si wà ninu awọn oniwa Sodomu.
15. On gba otoṣi ninu ipọnju rẹ̀, a si ṣi wọn li eti ninu inilara.
16. Bẹ̃ni pẹlupẹlu o si dẹ̀ ọ lọ lati inu ihagaga si ibi gbõrò, ti kò ni wahala ninu rẹ̀; ati ohun ti a si gbe kalẹ ni tabeli rẹ, a jẹ kiki ọ̀ra.