Job 36:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. O ṣi wọn leti pẹlu si ọ̀na ẹkọ́, o si paṣẹ ki nwọn ki o pada kuro ninu aiṣedede.

11. Bi nwọn ba gbagbọ, ti nwọn si sin i, nwọn o lò ọjọ wọn ninu ìrọra, ati ọdun wọn ninu afẹ́.

12. Ṣugbọn bi nwọn kò ba gbagbọ, nwọn o ti ọwọ idà ṣègbe, nwọn a si kú laini oye.

13. Ṣugbọn awọn àgabagebe li aiya kó ibinu jọ; nwọn kò kigbe nigbati o ba dè wọn.

14. Nigbana ni ọkàn wọn yio kú li ewe, ẹmi wọn a si wà ninu awọn oniwa Sodomu.

15. On gba otoṣi ninu ipọnju rẹ̀, a si ṣi wọn li eti ninu inilara.

16. Bẹ̃ni pẹlupẹlu o si dẹ̀ ọ lọ lati inu ihagaga si ibi gbõrò, ti kò ni wahala ninu rẹ̀; ati ohun ti a si gbe kalẹ ni tabeli rẹ, a jẹ kiki ọ̀ra.

17. Ṣugbọn iwọ kún fun idajọ awọn enia buburu; idajọ ati otitọ di ọ mu.

18. Nitori ibinu mbẹ, ṣọra ki titó rẹ ma bà tàn ọ lọ; má si ṣe jẹ ki titobi irapada mu ọ ṣìna.

Job 36