1. ELIHU si sọ si i lọ wipe,
2. Bùn mi laye diẹ, emi o si fi hàn ọ, nitori ọ̀rọ sisọ ni o kù fun Ọlọrun.
3. Emi o mu ìmọ mi ti ọ̀na jijin wá, emi o si fi ododo fun Ẹlẹda mi.
4. Nitoripe ọ̀rọ mi kì yio ṣeke nitõtọ, ẹniti o pé ni ìmọ wà pẹlu rẹ.
5. Kiyesi i, Ọlọrun li agbara, kò si gàn ẹnikẹni, o li agbara ni ipá ati oye.
6. On kì ida ẹmi enia buburu sí, ṣugbọn o fi otitọ fun awọn talaka.
7. On kì imu oju rẹ̀ kuro lara olododo, ṣugbọn pẹlu awọn ọba ni nwọn wà lori itẹ; ani o fi idi wọn mulẹ lailai, a si gbe wọn lekè.
8. Bi a ba si dè wọn ninu àba, ti a si fi okun ipọnju dè wọn,