6. Kiyesi i, bi iwọ jẹ ti Ọlọrun, bẹ̃li emi na; lati erupẹ wá ni a si ti dá mi pẹlu.
7. Kiyesi i, ẹ̀ru nla mi kì yio bà ọ, bẹ̃li ọwọ mi kì yio wuwo si ọ lara.
8. Nitõtọ iwọ sọ li eti mi, emi si gbọ́ ọ̀rọ rẹ wipe,
9. Emi mọ́, laini irekọja, alaiṣẹ li emi, bẹ̃li aiṣedede kò si li ọwọ mi.
10. Kiyesi i, ẹ̀fẹ li o fẹ si mi, o kà mi si ọ̀ta rẹ̀.
11. O kàn ẹsẹ mi sinu àba, o kiyesi ipa-irin mi gbogbo.