Job 33:19-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. A si fi irora nà a lori ibùsun rẹ̀, pẹlupẹlu a fi ijà egungun rẹ̀ ti o duro pẹ́, nà a.

20. Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn.

21. Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè ri i mọ́; egungun rẹ̀ ti a kò ri, si ta jade.

22. Ani ọkàn rẹ̀ sunmọ isa-okú, ati ẹmi rẹ̀ sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú.

23. Bi onṣẹ kan ba wà lọdọ rẹ̀, ẹniti nṣe alagbawi, ọkan ninu ẹgbẹrun lati fi ọ̀na pipé han ni:

24. Nigbana ni o ṣore-ọfẹ fun u, o si wipe, Gbà a kuro ninu ilọ sinu ihò, emi ti ri irapada!

25. Ara rẹ̀ yio si já yọ̀yọ̀ jù ti ọmọ kekere, yio si tún pada si ọjọ igba ewe rẹ̀.

26. O gbadura sọdọ Ọlọrun, on o si ṣe oju rere si i, o si mu enia ri oju rẹ̀ pẹlu ayọ̀, on o san ododo rẹ̀ pada fun enia.

27. O bojuwo enia, bi ẹnikan ba si wipe, Emi ṣẹ̀, mo si ti yi eyi ti o tọ́ po, a kò si sẹsan rẹ̀ fun mi;

28. O ti gba ọkàn mi kuro ninu ilọ sinu ihò, ẹmi mi yio si ri imọlẹ!

29. Wò o! nkan wọnyi li Ọlọrun imaṣe fun enia nigba meji, ati nigba mẹta,

30. Lati mu ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu ihò, lati fi imọlẹ alãyè mọ́ si i.

31. Jobu! kiyesi i gidigidi, ki o si fetisilẹ si mi; pa ẹnu rẹ mọ́, emi o si ma sọ!

32. Bi iwọ ba si ni ohun iwi, da mi lohùn, mã sọ, nitoripe emi nfẹ da ọ lare.

33. Bi bẹ̃ kọ̀, gbọ temi, pa ẹnu rẹ mọ́; emi o si kọ́ ọ li ọgbọ́n.

Job 33