Job 33:15-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ninu àla, li ojuran oru, nigbati orun ìjika ba kùn enia lọ, ni isunyẹ lori bùsun.

16. Nigbana ni iṣi eti enia, a si fi èdidi di ẹkọ wọn.

17. Ki o lè ifa enia sẹhin kuro ninu ete rẹ̀, ki o si pa igberaga mọ́ kuro lọdọ enia.

18. O si fa ọkàn rẹ̀ pada kuro ninu iho, ati ẹmi rẹ̀ lati ṣègbe lọwọ idà.

19. A si fi irora nà a lori ibùsun rẹ̀, pẹlupẹlu a fi ijà egungun rẹ̀ ti o duro pẹ́, nà a.

20. Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn.

21. Ẹran ara rẹ̀ rùn, titi a kò si fi lè ri i mọ́; egungun rẹ̀ ti a kò ri, si ta jade.

22. Ani ọkàn rẹ̀ sunmọ isa-okú, ati ẹmi rẹ̀ sunmọ ọdọ awọn iranṣẹ ikú.

Job 33