Job 33:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ nitorina, Jobu, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ mi, ki o si fetisi ọ̀rọ mi!

2. Kiyesi i nisisiyi, emi ya ẹnu mi, ahọn mi si sọ̀rọ li ẹnu mi.

3. Ọ̀rọ mi yio si jasi iduroṣinṣin ọkàn mi, ete mi yio si sọ ìmọ mi jade dajudaju.

4. Ẹmi Ọlọrun li o ti da mi, ati imisi Olodumare li o ti fun mi ni ìye.

5. Bi iwọ ba le da mi lohùn, tò ọ̀rọ rẹ lẹsẹsẹ niwaju mi, dide duro!

6. Kiyesi i, bi iwọ jẹ ti Ọlọrun, bẹ̃li emi na; lati erupẹ wá ni a si ti dá mi pẹlu.

7. Kiyesi i, ẹ̀ru nla mi kì yio bà ọ, bẹ̃li ọwọ mi kì yio wuwo si ọ lara.

8. Nitõtọ iwọ sọ li eti mi, emi si gbọ́ ọ̀rọ rẹ wipe,

9. Emi mọ́, laini irekọja, alaiṣẹ li emi, bẹ̃li aiṣedede kò si li ọwọ mi.

10. Kiyesi i, ẹ̀fẹ li o fẹ si mi, o kà mi si ọ̀ta rẹ̀.

11. O kàn ẹsẹ mi sinu àba, o kiyesi ipa-irin mi gbogbo.

12. Kiyesi i, ninu eyi iwọ ṣìna! emi o da ọ lohùn pe: Ọlọrun tobi jù enia lọ!

Job 33