Job 31:23-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Nitoripe iparun lati ọdọ Ọlọrun wá ni ẹ̀ru-nla fun mi, ati nitori Ọlanla rẹ̀ emi kò le iduro.

24. Bi o ba ṣepe mo fi wura ṣe igbẹkẹle mi, tabi bi mo ba wi fun wura didara pe, iwọ ni igbẹkẹle mi;

25. Bi mo ba yọ̀ nitori ọrọ̀ mi pọ̀, ati nitori ọwọ mi dẹ̀ lọpọlọpọ;

26. Bi mo ba bojuwo õrùn nigbati nràn, tabi òṣupa ti nrin ninu itan-imọlẹ,

27. Ti aiya mi si di titan, lati fi ẹnu mi kò ọwọ mi:

28. Eyi pẹlu li ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ lọdọ awọn onidajọ, nitoripe emi iba sẹ́ Ọlọrun ti o wà loke.

29. Bi o ba ṣepe mo yọ̀ si iparun ẹniti o korira mi, tabi bi mo ba si gbera soke, nigbati ibi bá a.

30. Bẹ̃li emi kò si jẹ ki ẹnu mi ki o ṣẹ̀ nipa fifẹ egún si ọkàn rẹ̀.

31. Bi awọn enia inu agọ mi kò ba le wipe, Tali o le ri ẹniti agbo-ẹran rẹ̀ kò tẹlọrùn?

32. Alejo kò wọ̀ ni igboro ri, emi ṣi ilẹkun mi silẹ fun èro.

33. Bi mo ba bò irekọja mi mọlẹ bi Adamu, ni pipa ẹbi mi mọ́ li aiya mi:

34. Ọ̀pọlọpọ enia ni mo ha bẹ̀ru bi, tabi ẹ̀gan awọn idile ni mba mi li ẹ̀ru? ti mo fi pa ẹnu mọ́, ti emi kò si fi jade sode?

35. Ibaṣepe ẹnikan le gbọ́ ti emi! kiyesi i, àmi mi! ki Olodumare ki o da mi lohùn! ki emi ki o si ri iwe na ti ọta mi ti kọ!

36. Nitõtọ emi iba gbe e le ejika mi, emi iba si dì i bi ade mọ́ ori mi.

37. Emi iba si sọ iye ìṣisẹ mi fun u, bi ọmọ-alade li emi iba sunmọ ọdọ rẹ̀.

38. Bi ilẹ mi ba si ke fi mi sùn, tabi ti aporo rẹ̀ pẹlu si sọkun,

39. Bi mo ba jẹ eso oko mi lainawo si i, tabi ti mo si mu ọkàn oluwa rẹ̀ fò lọ,

40. Ki ẹgun òṣuṣu ki o hù nipo alikama, ati wèpe nipo ọka-bàba. (Ọ̀rọ Jobu pari.)

Job 31