Job 31:12-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nitoripe iná ni eyi ti o jo de iparun, ti iba si fà gbongbo ohun ibisi mi gbogbo tu.

13. Bi mo ba si ṣe aikà ọ̀ran iranṣẹkunrin mi tabi iranṣẹbinrin mi si, nigbati nwọn ba mba mi jà;

14. Kili emi o ha ṣe nigbati Ọlọrun ba dide; nigbati o ba si ṣe ibẹwo, ohùn kili emi o dá?

15. Ẹniti o dá mi ni inu kọ li o da a? ẹnikanna ki o mọ wa ni inu?

16. Bi mo ba fà ọwọ sẹhin fun ifẹ-inu talaka, tabi bi mo ba si mu oju opó mofo;

17. Tabi ti mo ba nikan bu òkele mi jẹ, ti alainibaba kò jẹ ninu rẹ̀;

18. Nitoripe lati igba ewe mi wá li a ti tọ́ ọ dàgba pẹlu mi bi ẹnipe baba, emi si nṣe itọju rẹ̀ (opó) lati inu iya mi wá.

19. Bi emi ba ri olupọnju laini aṣọ, tabi talaka kan laini ibora;

20. Bi ẹgbẹ rẹ̀ kò ba sure fun mi, tabi bi ara rẹ̀ kò si gbona nipasẹ irun agutan mi.

21. Bi mo ba si gbe ọwọ mi soke si alainibaba, nitoripe mo ri iranlọwọ mi li ẹnu-bode,

22. Njẹ ki apá mi ki o wọ́n kuro li ọkọ́ ejika rẹ̀, ki apá mi ki o si ṣẹ́ lati egungun rẹ̀ wá.

23. Nitoripe iparun lati ọdọ Ọlọrun wá ni ẹ̀ru-nla fun mi, ati nitori Ọlanla rẹ̀ emi kò le iduro.

24. Bi o ba ṣepe mo fi wura ṣe igbẹkẹle mi, tabi bi mo ba wi fun wura didara pe, iwọ ni igbẹkẹle mi;

25. Bi mo ba yọ̀ nitori ọrọ̀ mi pọ̀, ati nitori ọwọ mi dẹ̀ lọpọlọpọ;

26. Bi mo ba bojuwo õrùn nigbati nràn, tabi òṣupa ti nrin ninu itan-imọlẹ,

27. Ti aiya mi si di titan, lati fi ẹnu mi kò ọwọ mi:

28. Eyi pẹlu li ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ lọdọ awọn onidajọ, nitoripe emi iba sẹ́ Ọlọrun ti o wà loke.

29. Bi o ba ṣepe mo yọ̀ si iparun ẹniti o korira mi, tabi bi mo ba si gbera soke, nigbati ibi bá a.

30. Bẹ̃li emi kò si jẹ ki ẹnu mi ki o ṣẹ̀ nipa fifẹ egún si ọkàn rẹ̀.

Job 31