Job 31:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI ti bá oju mi da majẹmu, njẹ emi o ha ṣe tẹjumọ wundia?

2. Nitoripe kini ipin Ọlọrun lati ọrun wá, tabi kini ogún Olodumare lati oke ọrun wá?

3. Kò ṣepe awọn enia buburu ni iparun wà fun, ati ìṣẹniṣẹ fun awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ?

4. On kò ha ri ipa-ọ̀na mi, on kò ha si ka gbogbo iṣiṣe mi?

5. Bi o ba ṣepe emi ba fi aiṣotitọ rìn, tabi ti ẹsẹ mi si yara si ẹ̀tan.

6. Ki a diwọn mi ninu iwọ̀n ododo, ki Ọlọrun le imọ̀ iduroṣinṣin mi.

7. Bi ẹsẹ mi ba yà kuro loju ọ̀na, ti aiya mi si tẹ̀le ipa oju mi, bi àbawọn kan ba si lẹmọ́ mi li ọwọ.

8. Njẹ ki emi ki o gbìn ki ẹlomiran ki o si mu u jẹ, ani ki a fà iru-ọmọ mi tu.

9. Bi aiya mi ba di fifa sipasẹ obinrin kan, tabi bi mo ba lọ ibadeni li ẹnu-ọ̀na ile aladugbo mi,

10. Njẹ ki aya mi ki o lọ ọlọ fun ẹlomiran, ki awọn ẹlomiran ki o tẹ̀ ara wọn li ara rẹ̀.

11. Nitoripe ẹ̀ṣẹ buburu li eyi; ani ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ ni lọdọ awọn onidajọ.

Job 31