6. Lati gbé inu pàlapala okuta afonifoji, ninu iho ilẹ ati ti okuta.
7. Ninu igbẹ ni nwọn ndún, nwọn ko ara wọn jọ pọ̀ labẹ ẹgun neteli.
8. Awọn ọmọ ẹniti oye kò ye, ani ọmọ awọn enia lasan, a si le wọn kuro ninu ilẹ.
9. Njẹ nisisiyi emi di ẹni-orin fun wọn, ani emi di ẹni-asọrọsi fun wọn.
10. Nwọn korira mi, nwọn sa kuro jina si mi, nwọn kò si dá si lati tutọ́ si mi loju.
11. Nitoriti Ọlọrun ti tu okun-ìye mi, o si pọn mi loju; awọn pẹlu si dẹ̀ ijanu niwaju mi.