Job 3:16-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Tabi bi ọlẹ̀ ti a sin, emi kì ba ti si; bi ọmọ iṣẹnu ti kò ri imọlẹ.

17. Nibẹ ni ẹni-buburu ṣiwọ iyọnilẹnu, nibẹ ẹni-ãrẹ̀ wà ninu isimi.

18. Nibẹ ni awọn ìgbekun simi pọ̀, nwọn kò si gbohùn amunisìn mọ́.

19. Ati ewe ati àgba wà nibẹ, ẹru si di omnira kuro lọwọ olowo rẹ̀.

Job 3