1. LẸHIN eyi ni Jobu yanu o si fi ọjọ ibi rẹ̀ ré.
2. Jobu sọ, o si wipe,
3. Ki ọjọ ti a bi mi ki o di igbagbe, ati oru nì, ninu eyi ti a wipe; a loyun ọmọkunrin kan.
4. Ki ọjọ na ki o jasi òkunkun, ki Ọlọrun ki o má ṣe kà a si lati ọrun wá, bẹ̃ni ki imọlẹ ki o máṣe mọ́ si i.
5. Ki òkunkun ati ojiji ikú fi ṣe ti ara wọn: ki awọsanma ki o bà le e, ki iṣúdùdu ọjọ na ki o pa a laiya.
6. Ki òkunkun ki o ṣúbo oru na biribiri, ki o má ṣe yọ̀ pẹlu ọjọ ọdun na: ki a má ṣe kà a mọ iye ọjọ oṣù.
7. Ki oru na ki o yàgan; ki ohùn ayọ̀ kan ki o má ṣe wọnu rẹ̀ lọ.
8. Ki awọn ti ifi ọjọ gegun ki o fi i gegun, ti nwọn muratan lati rú Lefiatani soke.
9. Ki irawọ̀ ofẽfe ọjọ rẹ̀ ki o ṣokùnkun; ki o ma wá imọlẹ, ṣugbọn ki o má si, bẹ̃ni ki o má ṣe ri afẹmọjumọ́.
10. Nitoriti kò se ilẹkun inu iya mi, bẹ̃ni kó si pa ibinujẹ mọ́ kuro li oju mi.
11. Ẽṣe ti emi kò fi kú lati inu wá, tabi ti emi kò fi pin ẹmi nigbati mo ti inu jade wá?