Job 29:15-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Mo ṣe oju fun afọju, ati ẹsẹ̀ fun amọkún.

16. Mo ṣe baba fun talaka, ati ọ̀ran ti emi kò mọ̀, mo wadi rẹ̀ ri.

17. Mo si ká ehin ẹ̀rẹkẹ enia buburu, mo si ja ohun ọdẹ na kuro li ehin rẹ̀.

18. Nigbana ni mo wipe, emi o kú ninu itẹ mi, emi o si mu ọjọ mi pọ̀ si i bi iyanrin. (bi ọjọ ti ẹiyẹ Feniksi.)

19. Gbongbo mi ta lọ si ibi omi, ìri si sẹ̀ si ara ẹká mi titi li oru.

20. Ogo mi gberu lọdọ mi, ọrun mi si pada di titun li ọwọ mi.

Job 29