Job 26:5-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀.

6. Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.

7. On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.

8. O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.

9. O si fa oju itẹ rẹ̀ sẹhin, o si tẹ awọ sanma rẹ̀ si i lori.

10. O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun.

11. Ọwọn òpo ọrun wáriri, ẹnu si yà wọn si ibawi rẹ̀.

12. O fi ipa rẹ̀ damu omi-okun, nipa oye rẹ̀ o lu agberaga jalẹjalẹ.

13. Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì.

14. Kiyesi i, eyi ni opin ọ̀na rẹ̀, ohùn eyiti a gbọ́ ti kere tó! ṣugbọn ãra ipá rẹ̀ tali oye rẹ̀ le iye?

Job 26