5. Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀.
6. Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.
7. On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.
8. O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.
9. O si fa oju itẹ rẹ̀ sẹhin, o si tẹ awọ sanma rẹ̀ si i lori.
10. O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun.
11. Ọwọn òpo ọrun wáriri, ẹnu si yà wọn si ibawi rẹ̀.
12. O fi ipa rẹ̀ damu omi-okun, nipa oye rẹ̀ o lu agberaga jalẹjalẹ.
13. Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì.