Job 25:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA ni Bildadi, ara Ṣua, dahùn wipe,

2. Ijọba ati ẹ̀ru mbẹ lọdọ rẹ̀, on ni iṣe ilaja ni ibi gigagiga rẹ̀.

3. Awọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ni iye bi, tabi ara tani imọlẹ rẹ̀ kò mọ́ si?

4. Eha ti ṣe ti a o fi da enia lare lọdọ Ọlọrun, tabi ẹniti a bi lati inu obinrin wá yio ha ṣe mọ́?

5. Kiyesi i, òṣupa kò si le itan imọlẹ, ani awọn ìrawọ kò mọlẹ li oju rẹ̀.

Job 25