Job 22:7-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Iwọ kò fi omi fun alãrẹ mu, iwọ si hawọ onjẹ fun ẹniti ebi npa.

8. Bi o ṣe ti alagbara nì ni, on li o ni aiye, ọlọla si tẹdo sinu rẹ̀.

9. Iwọ ti rán awọn opó pada lọ li ọwọ ofo, apa awọn ọmọ alainibaba ti di ṣiṣẹ́.

10. Nitorina ni idẹkun ṣe yi ọ kakiri, ati ìbẹru ojiji nyọ ọ lẹnu.

11. Tabi iwọ kò ha ri okunkun, ati ọ̀pọlọpọ omi ti o bò ọ mọlẹ?

12. Ọlọrun kò ha jẹ Ẹni giga ọrun? sa wò ori awọn ìrawọ̀ bi nwọn ti ga tó!

13. Iwọ si wipe, Ọlọrun ti ṣe mọ̀, on ha le iṣe idajọ lati inu awọsanma dudu wá bi?

14. Awọsanma ti o nipọn ni ibora fun u, ti kò fi le riran; o si rin ninu ayika ọrun.

15. Iwọ fẹ rìn ipa-ọ̀na igbani ti awọn enia buburu ti rìn.

16. Ti a ke lulẹ kuro ninu aiye laipé ọjọ wọn, ipilẹ wọn ti de bi odò ṣiṣàn.

17. Awọn ẹniti o wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa! Kini Olodumare yio ṣe fun wọn.

Job 22