Job 22:25-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nigbana ni Olodumare yio jẹ iṣura rẹ, ani yio si jẹ fadaka fun ọ ni ọ̀pọlọpọ.

26. Lotitọ nigbana ni iwọ o ni inu didùn ninu Olodumare, iwọ o si gbe oju rẹ soke sọdọ Ọlọrun.

27. Bi iwọ ba gbadura rẹ sọdọ rẹ̀, yio si gbọ́ tirẹ, iwọ o si san ẹ̀jẹ́ rẹ.

28. Iwọ si gbimọ ohun kan pẹlu, yio si fi idi mulẹ fun ọ; imọlẹ yio si mọ́ sipa ọ̀na rẹ.

29. Nigbati ipa-ọ̀na rẹ ba lọ sisalẹ, nigbana ni iwọ o wipe, Igbesoke mbẹ! Ọlọrun yio si gba onirẹlẹ là!

30. Yio gba ẹniti kì iṣe alaijẹbi là, a o si gbà a nipa mimọ́ ọwọ rẹ.

Job 22