9. Ile wọn wà laini ewu, bẹ̃ni ọpa-ìna Ọlọrun kò si lara wọn.
10. Akọ-malu wọn a ma gùn, kì isi isé, abomalu wọn a ma bi, ki isi iṣẹnu;
11. Nwọn a ma rán awọn ọmọ wọn wẹwẹ jade bi agbo ẹran, awọn ọmọ wọn a si ma jó.
12. Nwọn mu ohun ọnà orin timbreli ati dùru, nwọn si nyọ̀ si ohùn ifère.
13. Nwọn lo ọjọ wọn ninu ọrọ̀; ni iṣẹjukan nwọn a lọ si ipo-okú.
14. Nitorina ni nwọn ṣe wi fun Ọlọrun pe, Lọ kuro lọdọ wa, nitoripe awa kò fẹ ìmọ ipa ọ̀na rẹ!
15. Kini Olodumare ti awa o fi ma sin i? ere kili a o si jẹ bi awa ba gbadura si i!
16. Kiyesi i, alafia wọn kò si nipa ọwọ wọn, ìmọ enia buburu jina si mi rére.
17. Igba melomelo ni a npa fitila enia buburu kú? igba melomelo ni iparun wọn de ba wọn, ti Ọlọrun isi ma pin ibinujẹ ninu ibinu rẹ̀.
18. Nwọn dabi akeku oko niwaju afẹfẹ, ati bi iyangbo, ti ẹfufu-nla fẹ lọ.